ÌLÒ Ẹ̀FẸ̀ FÚN YÍYANJÚ ÌṢÒRO ÌBÁRA-ẸNI-GBÉ-PỌ̀ AJẸMÓṢÈLÚ GẸ́GẸ́ BÍÓ ṢEHÀN NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN YORÙBÁ

Authors

  • Adágbádá , O. O Olabisi Onabanjo University, Ago-Iwoye Author
  • Adéfowópè , G.O. Our Lady of Apostles Secondary School (Private), Ijebu-Ode Author

DOI:

https://doi.org/10.2023/p3apmx92

Keywords:

Ẹ̀fẹ̀ , Ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ , Ìkóra-ẹni-ní jàánu, Ìṣòro, Ìṣè lu

Abstract

Ipò tí àwù jọ wà nípa è tò òṣè lú bó-o-ba-o-pá , bó-ò-ba-o-bù-ú-lẹ́sẹ̀ , ì
rẹ́nijẹ, ìṣowó ìlú mọ́kumọ̀ku, jàgídí jàgan à ti àwọn ìwà ìbà jẹ́ mìí ràn tí ó gbilẹ̀ lágbo òṣè lú ni ó bí iṣẹ́ ìwádì í yìí. Èròńgbà iṣẹ́ ìwádì í yì í ni lá ti wò bí ìlò ẹ̀ fẹ̀ ṣe lè yanjú ìṣòro ìbára-ẹni-gbé-pọ̀ nínú ètò ìṣèlú, nípa fífi òó
tọ́ ọ̀rọ̀gún aṣebi lára, kí èyílèjẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn ẹlòmíràn, tí yóò sì
tún kọ́ àwùjọ ní ẹ̀kọ́ìwàì-kóraẹni-níjàánu àti ìwà ọmọlúàbí. Ọgbọ́n ìṣèwádìí tíiṣẹ́ ìwádìí yìí tọ̀ ni ṣíṣe ìtúpalẹ̀ kíkún lórí àkóónú àwọn ìwé mé
jì tí a ṣà yàn fún ìtúpalẹ̀lórí bí àwọn òǹkọ̀wé ṣe lo ẹ̀fẹ̀, láti yanjú àwọn ìṣòro ìbára ẹni-gbé-pọ̀ ajẹmóṣèlú. Àwọn ìwé eré-onítàn ajẹmẹ́fẹ̀ ní èdè Yorùbátí a yàn ni Orí Mẹ̀kúnnù àtiÀgbò Orí-Ìso. Tíọ́rììfojú-ìmọ̀-ìbára-ẹni-gbé-pọ̀-àwùjọ-wò-lítíréṣọ̀ (Sociology of Literature) àti tíọ́rì ìmọ̀ Ìlò-Àmì Ajẹmáwùjọ (Social-Semiotic) ni ọ̀pákùtẹ̀ lẹ̀tíiṣẹ́ìwádìí yìírọ̀ mọ́, láti wo bí
ìlò ẹ̀fẹ̀ ṣe lè dẹ́kun àwọn ìwà ìbàjẹ́ ní agbo òṣèlú, nìwọn ìgbàtí ójẹ́ pé àwùjọ ni àwọn olóṣèlú ń ṣe ìjọba lé lórí àti péinú àwùjọ ni lítíréṣọ̀ ti hù
jáde. Iṣẹ́ìwádìí yìíṣe àwárí péìlò ẹ̀fẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìfòótọ́-ọ̀rọ̀-gúnni-lára, lè kọ́ àwọn olóṣèlú àti àwọn tí ó wà nídìí ètò ìṣàkóso ní ẹ̀kọ́ ìwà ì-kóra-ẹni
níjàánu, tíìfọ̀kànbalẹ̀ àti àlàáfíà yóò sìjọbá ní àwùjọ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹ yọ nínú àwọn àṣàyàn ìwé àmúlò. Ìgúnlẹ̀iṣẹ́ìwádìí yìí ni pé kiìjọba àti àwùjọ máfi ojú rénà àwọn àṣàilẹ̀ wa pátápátá, kí afi àyè gba ìlò ẹ̀fẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ijánu fún ìwà ìbàjẹ́, kí ẹ̀míìkóra-ẹni-níjàánu lèfẹsẹ̀ múlẹ̀ síi ní àwùjọ, pàápàá ní agbo òṣèlú. Yàtọ̀ sí èyí, kí ètò ààbò àti ti ìdájọ́ má dijú sí ẹjọ́
títa-lólobó ìwà ìbàjẹ́ nínú ẹ̀fẹ̀ tí wọ́n báfi àwọn aṣèbàjẹ́ lágbo òṣèlú ṣe, kí wọ́n lè yíìwà padà. Bákan náà, kí àwọn olóṣèlú típẹ̀tẹ̀pẹ́ tẹ̀ ẹ̀fẹ̀ bá ta sí
lára gbìyànjúláti ṣe àtúnṣe. 

Downloads

Download data is not yet available.

Author Biography

  • Adágbádá , O. O, Olabisi Onabanjo University, Ago-Iwoye

    Department of Linguistics and Nigerian Languages

Published

2025-06-01

How to Cite

ÌLÒ Ẹ̀FẸ̀ FÚN YÍYANJÚ ÌṢÒRO ÌBÁRA-ẸNI-GBÉ-PỌ̀ AJẸMÓṢÈLÚ GẸ́GẸ́ BÍÓ ṢEHÀN NÍNÚ ÀWỌN ÀṢÀYÀN ÌWÉ ERÉ-ONÍTÀN YORÙBÁ. (2025). COEASU Erudite Journal, 6(1). https://doi.org/10.2023/p3apmx92